- f Gbogbo aiye, gbe Jesu ga,
di Angẹl, ẹ wolẹ fun;
cr Ẹ mu ade Ọba Rẹ̀ wa,
Ṣe l’Ọba awọn ọba.
- mf Ẹ ṣe l’Ọba, ẹnyin Martyr,
Ti npè ni pẹpẹ Rẹ̀;
cr Gbe gbongbo-igi Jesse ga,
f Ṣe l’Ọba awọn oba.
- mf Ẹnyin iru-ọmọ Israẹl,
Ti a ti rapadà;
cr Ẹ ki Ẹnit’ o gbà nyin là,
f Ṣe l’Ọba awọn oba.
- p Gbogbo enia ẹlẹṣẹ,
Ranti ‘banujẹ nyin;
cr Ẹ tẹ́ ‘kogun nyin s’ẹsẹ Rẹ̀,
f Ṣe l’Ọba awọn oba.
- ff Ki gbogbo orilẹ-ede,
Ni gbogbo agbaiye;
Ki nwọn ki, “Kabiyesilẹ,”
Ṣe l’Ọba awọn oba.
- mf A ba le pẹl’ awọn t’ọrun,
Lati ma juba Rẹ̀;
cr K’a ba le jọ jumọ kọrin,
ff Ṣe l’Ọba awọn oba. Amin.