- mf L’okọ Jesu, gbogbo ekun yio wolẹ̀,
Ahọn yio jẹwọ Rẹ̀ pe On l’Ọba ogo;
Ifẹ Baba ni pe, k’a pe l’ Oluwa,
cr Ẹnit’ iṣe Ọ̀rọ lat’ aiyeraiye.
- f Nipa Ọrọ Rẹ̀ l’a dá ohun gbogbo,
Awọn angẹli at’ awọn imolẹ,
Itẹ, ijoba, at’ awọn irawọ,
Gbogbo ẹda ọrun ninu ogun wọn.
- p O rẹ̀ ‘ra Rẹ̀ silẹ, lati gb’ orukọ,
Lọdọ awọn ẹlẹṣẹ t’o wa ku fun;
cr Ko jẹ ki ẹ̀gàn bà lé orukọ yi,
Titi O fi jinde t’a si ṣe l’ogo.
- mf Orukọ yi lo f’ayọ gbe lọ s’ọrun,
cr Kọja gbogbo ẹda lọ sibi giga,
f S’ itẹ Ọlọrun, ọ’okan aiya Baba,
O si fi ogo isimi pipe kun.
- f F’ ifẹ darukọ Rẹ̀, ẹnyin ará, wa
p Pẹlu ẹ̀ru jẹ̀jẹ̀ ati iyanu,
mf Ọlọrun Oluwa, Krist, Olugbala,
cr Titi lao ma sin Ọ, ao ma tẹriba.
- mf Ẹ jẹ ki Jesu jọba n’nu ọkàn nyin;
Y’o mu ohun buburu gbogbo kuro;
cr Ṣe l’ ọgagun nyin l’akoko idanwò;
Ẹ jẹ ki ‘fẹ Rẹ̀ jẹ odi yi nyin ka.
- f Arakunrin, Jesu yi yio tun padà,
N’nu ogo Baba, pẹl’ awọn angẹli;
ff Gbogbo orilẹ-ede y’o wárí fun,
Ọkàn wa y’o jẹwọ pe, On ni Ọba. Amin.