- f Alleluya ! orin t’o dùn,
Ohùn ayọ̀ ti ki ku:
Alleluya ! orin didun,
T’ awọn t’o wà lọrun fẹ;
N’ile ti Ọlọrun mi ngbe,
Ni nwọn nkọ tọsantoru.
- Alleluya ! Ijọ ọrun,
Ẹ le kọrin ayọ̀ na.
Alleluya ! orin ‘ṣẹgun
Yẹ awọn t’a rapada.
Awa èro at’ alejo,
di Iyin wa kò nilari.
- mp Alleluya ! orin ayọ
Kò yẹ wa nigbagbogbo.
Alleluya ! ohùn arò
Dà mọ orin ayọ̀ wa;
p Gbat a wà laiye oṣi yi,
di A ni gbawẹ f’ ẹ̀ṣẹ wa.
- cr Iyìn dàpọ m’ adua wa;
Gbo tiwa, Mẹtalọkan !
mf Mu wa de ‘waju Rẹ layọ̀,
K’a r’ Ọdagutan t’a pa:
f K’a le ma kọ Alleluya
Nibẹ lai ati lailai. Amin.