Hymn 588: O! Hear our Prayer O! God of Host

Gb’ adura wa, Oba aiye

  1. mf Gb’ adurà wa, Ọba aiye,
    ‘Gbat’ a wolẹ fun Ọ;
    f Gbogbo wa nkigbe n’ irẹlẹ̀,
    di A mbẹbẹ fun anu.
    Tiwa l’ ẹbi, Tirẹ l’ anu,
    Màṣe le wa pada;
    Ṣugbọn gbọ́ ‘gbe wa n’itẹ Rẹ,
    Ran adura wa lọwọ.

  2. p Ẹṣẹ awọn baba wa pọ̀,
    Tiwa kò si kere;
    Ṣugbọn lati irandiran,
    L’O ti f’ ore Rẹ hàn.
    Nigba ewu, b’omi jijà,
    Yi ilu wa yi ka,
    Iwọ l’a wo, t’a si kepè,
    K’ a ma ri ranwọ Rẹ.

  3. p L’ ohùn kan, gbogbo wa wolẹ̀,
    L’ abẹ ibawi Rẹ;
    Gbogbo wa njẹwọ ẹ̀ṣẹ wa,
    A ngbawẹ fun ‘lẹ̀ wa.
    F’ oju anu wo aini wa,
    Bi a ti nkepe Ọ;
    Fi idajọ Rẹ ba wa wi,
    Da wa si l’ anu Rẹ. Amin.