- f Ẹnyin ‘ranṣẹ Kristi,
Gbọ́ ohun ipè Rẹ̀;
Ẹ tẹle ‘bi t’ o fọnahàn,
A npè nyin s’ ọnà Rẹ̀.
- Baba ti ẹnyin nsìn,
O n’ ipa to fun nyin;
N’ igbẹkẹle ileri Rẹ̀,
f Ẹ jà bi ọkùnrin.
- Lọ f’ Olugbala hàn,
p Ati anu nla Rẹ̀;
F’ awọn otoṣi ẹlẹṣẹ,
Ninu ọmọ Adam.
- f L’ orukọ Jesu wa,
cr A kí nyin, “Ọnà re!”
A mbẹ Ẹnit’ o rán nyin lọ,
K’O busi iṣẹ nyin. Amin.