- mf “Mọlẹ t’o da gbogbo nkan,
Ni pípé, lati ‘n’ okùn,
cr K’a pin n’ n’ẹwà on’ bukun Rẹ.
Wa sọdọ wa.
- f IMọlẹ t’o jọba aiye,
‘Mọlẹ t’o fun wa n’ìye;
A! Imọlẹ t’o nṣ’atùnda,
Wa ṣọdọ wa.
- p Imọlẹ t’o wá s’ aiye,
“Mọlẹ t’o nw’oju ẹda,
pp T’o kú l’okunkun b’enia.
Wa ṣọdọ wa.
- cr ‘Mọlẹ t’ o de ‘pò ‘rẹlẹ,
T’o tun lọ soke giga,
T’o si wà pẹlu wa sibẹ,
Wa ṣọdọ wa.
- mf “Mọlẹ t’o nfun wa l’oye,
‘Mọlẹ t’o nṣe wa lẹwà,
Imọlẹ ti nf’ayọ̀ simi,
Wa ṣọdọ wa.
- mp Maṣe jẹ k’a pe a rí,
‘Gbat’a diju wa si Ọ,
pp Ẹnit’o nfi suru kànkùn,
Wa ṣọdọ wa.
- mf Tirẹ ni gbogbo ‘re wa;
Tiwa ni gbogbo ibi;
Jọ le wọn kuro lọdọ Rẹ,
Wa ṣọdọ wa.
- Mu ‘ṣẹ okunkun kuro;
Di wa ni hamọra Rẹ,
cr K’a rin n’nu ‘mọlẹ k’a ma ṣọ
Atunwa Rẹ.
- p Awa ṣẹ̀ Ọ pupọ ju,
cr Sibẹ Tirẹ l’awa ọe;
Jẹ k’aiye wa j’orin si Ọ,
Wa ṣọdọ wa.
- Wa ninu Ọlanla Rẹ,
di Ni titobi ‘rẹ̀lẹ Rẹ;
ff Wa, gbogbo aiye nkepè Ọ.
Wa ṣọdọ wa. Amin.