- Onidajọ mbọ wá,
Awọn oku jinde,
Ẹnikan ko lè yọ kuro
‘Nu mọlẹ oju Rẹ̀.
- Ẹnu ododo Rẹ̀
Yio da ẹbi fun
Awọn t’ o sọ anu Rẹ̀ nu;
Ti nwọn ṣe buburu.
- “Lọ kuro lọdọ mi
S’ iná ‘ti ko l’opin
Ti a ti pesè fun Esu
T’ o ti nṣọtẹ̀ si mi.”
- Iwọ ti duro to!
Ọjọ na o mbọ wá,
T’ aiye at’ ọrun o fò lọ
Kuro ni wiwá Rẹ̀. Amin.