mf Ẹ ji enyin enia Ẹ má ṣe sun titi; f A! Imọlẹ wa nlanlà On li o yọ de yi. Orùn n’ imọlẹ ara, Jesu ni ti ọkàn? Ireti awọn baba Yio ha de lasan?
p O de k’ ẹwọ̀n ẹ̀ṣẹ tú O de k’ okunkun lọ; f Ẹ yò, ijọba Jesu O ni rọrun pupọ, Ẹ jẹ k’ a mu ọrẹ wá K’ a juba Ọba wa Awọn amoye mu wá A kì o mu wá bi?
f Je k’ a fi ọkàn wa fùn, K’ o tẹ ‘tẹ Rẹ̀ sibẹ; K’ a fi ohun gbogbo fun K’ a si ṣe ifẹ Rè. ff Ẹ yọ̀! ẹ yọ̀! ẹ tun yọ̀! Jesu Oluwa de F’ otoṣi at’ ọlọrọ, Kristi Oluwa de. Amin.