- f Ọjọ ayọ̀ nlanla na de,
Eyi t’ araiye ti nreti;
cr Nigbat’ Olugbala w’aiye
Nigbat’ a bi ninu ara.
- f Oluṣagutan ni pápá
Bi nwọn ti nṣọ agutan wọn,
Ni ihin ayọ na kọ̀ bá.
Ihin bibi Olugbala.
- Angel iranṣẹ Oluwa
L’ a ran si wọn, alabukun,
Pẹlu ogo t’ o tan julọ,
Lati sọ ihin ayọ̀ yi.
- mp Gidigidi l’ ẹ̀ru bà wọn,
Fun ajeji iran nla yi:
f “Má bẹru” l’ ọ̀rọ iyanju
T’ o t’ ẹnu Angẹli na wá.
- A bi Olugbala loni,
Kristi Oluwa aiye ni;
N’ ilu nla Dafidi l’ o wà,
p N’ ibujẹ ẹran l’ a tẹ si.
- f “Ogo fun Ọlọrun” l’ orin
Ti enia y’o kọ s’ ọrun;
Fun ifẹ Rẹ̀ laini opin,
T’ o mu alafia w’ aiye. Amin.